Mark 3:13-19

Jesu yan àwọn aposteli méjìlá

13 aJesu gun orí òkè lọ, ó sì pe àwọn kan tí ó yàn láti wà pẹ̀lú rẹ̀, wọ́n sì tọ̀ ọ́ wá. 14Ó yan àwọn méjìlá, kí wọn kí ó lè wà pẹ̀lú rẹ̀, àti kí ó lè rán wọn lọ láti wàásù 15àti láti lágbára láti lé àwọn ẹ̀mí Èṣù jáde.

16 bWọ̀nyí ni àwọn méjìlá náà tí ó yàn:

Simoni (ẹni ti ó sọ àpèlé rẹ̀ ní Peteru)
17Jakọbu ọmọ Sebede àti Johanu arákùnrin rẹ̀ (àwọn ẹni tí Jesu sọ àpèlé wọ́n ní Boanaji, èyí tí ó túmọ̀ sí àwọn ọmọ àrá).
18Àti Anderu,
Filipi,
Bartolomeu,
Matiu,
Tomasi,
Jakọbu ọmọ Alfeu,
Taddeu,
Simoni tí ń jẹ́ Sealoti (ọ̀kan nínú àwọn ẹgbẹ́ tí o ń ja fun òmìnira àwọn Júù).
19 cÀti Judasi Iskariotu, ẹni tí ó fi í hàn níkẹyìn.
Copyright information for YorBMYO